Psalms 124

Orin fún ìgòkè. Ti Dafidi.

1“Ìbá má ṣe pé Olúwa tí ó ti wà fún wa”
ni kí Israẹli kí ó máa wí nísinsin yìí;
2“Ìbá má ṣe pé Olúwa tó wà ní tiwa,”
Nígbà tí àwọn ènìyàn dúró sí wa:
3Nígbà náà ni wọn ò bá gbé wà mì láààyè
nígbà tí ìbínú wọn ru sí wa
4Nígbà náà ni omi
wọ̀n-ọn-nì ìbá bò wá mọ́lẹ̀
5Nígbà náà ni agbéraga
omi ìbá borí ọkàn wa.

6Olùbùkún ni Olúwa, tí kò fi wá fún wọ́n
bí ohun ọdẹ fún eyín wọn.
7Ọkàn wa yọ bí ẹyẹ jáde kúrò nínú okùn apẹyẹ;
okùn já àwa sì yọ.
8Ìrànlọ́wọ́ wa ń bẹ ní orúkọ Olúwa,
tí ó dá ọ̀run òun ayé.
Copyright information for YorBMYO